Yoruba Hymn 81 APA - Gbo eda orun nkorin

Yoruba Hymn 81 APA - Gbo eda orun nkorin

Yoruba Hymn 81 APA - Gbo eda orun nkorin

APA 81

 1. Gbo eda orun nkorin,

 “Ogo fun Oba t’ a bi”.

 “Alafia laiye yi”

 Olorun ba wa laja.

 Gbogbo eda, nde layo,

 Dapo mo hiho orun;

 W’ Alade Alafia !

 Wo Orun ododo de.


2. O bo ’go Re sapakan,

 A bi k’ enia ma ku,

 A bi k’ o gb’ enia ro,

 A bi k’ o le tun wa bi.

 Wa, ireti enia,

 Se ile Re ninu wa;

 N’ de, Iru Omobinrin,

 Bori Esu ninu wa.


3. Pa aworan Adam run,

 F’ aworan Re s’ ipo re;

 Jo, masai f’ Emi Re kun

 Okan gbogb’ onigbagbo.

 “Ogo fun Oba t’ a bi,”

 Je ki gbogbo wa gberin,

 “Alafia laiye yi,”

 Olorun ba wa laja. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 81 - Gbo eda orun nkorin . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post