Yoruba Hymn APA 212 - Wo t’ o mbebe f’ ota Re

Yoruba Hymn APA 212 - Wo t’ o mbebe f’ ota Re

Yoruba Hymn  APA 212 - Wo t’ o mbebe f’ ota Re

APA 212

 1. ’Wo t’ o mbebe f’ ota Re,

 L’ or’ igi agbelebu:

 Wipe, “fiji won Baba:”

 Jesu, sanu fun wa.


2. Jesu, jo bebe fun wa,

 Fun ese wa gbagbogbo;

 A ko mo ohun t’ a nse:

 Jesu, sanu fun wa.


3. Je k’ awa ti nwa anu,

 Dabi Re l’ okan n’ iwa,

 ’Gbat’ a ba se wa n’ibi:

 Jesu, sanu fun wa.


4. Jesu, ’Wo t’ o gbo aro

 Ole t’ o ku l’egbe Re,

 T’ o si mu d’ orun rere:

 Jesu, sanu fun wa.


5. Ninu ebi ese wa,

 Je k’ a toro anu Re,

 K’ a ma pe oruko Re:

 Jesu, sanu fun wa.


6. Ranti awa ti nrahun,

 T’ a nwo agbelebu Re;

 F’ ireti mimo fun wa,

 Jesu, sanu fun wa.


7. ’Wo t’ o fe l’ afe dopin

 Iya Re t’ o nkanu Re,

 Ati ore Re owon:

 Jesu, sanu fun wa.


8. Je k’ a pin n’nu iya Re,

 K’ a ma ko iku fun O,

 Je k’ a ari toju Re gba:

 Jesu, sanu fun wa.


9. Ki gbogbo awa Tire

 Je omo ile kanna;

 ’Tori Re, k’ a f era wa:

 Jesu, sanu fun wa.


10. Jesu, ’Wo ti eru mba,

 ’Gbat’ o si ku ’Wo nikan,

 Ti okunkun su bo O:

 Jesu, sanu fun wa.


11. ’Gbati a ba npe lasan,

 T’ ire wa si jina;

 N’nu okun na di wa mu:

 Jesu, sanu fun wa.


12. B’ o dabi Baba ko gbo,

 B’ o dabi ’mole ko si,

 Je k’ a f’igbagbo ri O,

 Jesu, sanu fun wa.


13. Jesu, ninu ongbe Re,

 Ni ori agbelebu,

 ’Wo ti o few a sibe:

 Jesu, sanu fun wa.


14. Ma kongbe fun wa sibe,

 Sise mimo l’ ara wa;

 Te ife Re na l’ orun;

 Jesu, sanu fun wa.


15. Je k’ a kongbe ife Re,

 Ma samona wa titi,

 Sibi omi iye ni;

 Jesu, sanu fun wa.


16. Jesu Olurapada,

 ’Wo t’ se ’fe Baba Re,

 T’ o si jiya ’tori wa;

 Jesu, sanu fun wa.


17. Gba wa l’ ojo idamu,

 Se oluranlowo wa,

 Lati ma t’ ona mimo;

 Jesu, sanu fun wa.


18. F’ imole Re s’ona wa,

 Ti y’o ma tan titi lai,

 Tit’ ao fi de odo Re:

 Jesu, sanu fun wa.


19. Jesu, gbogbo ise Re,

 Gbogbo ijamu Re pin;

 O jow’ emi Re lowo;

 Jesu, sanu fun wa.


20. ’Gbat’ iku ba de ba wa,

 Gba wa lowo ota wa;

 Yo wa ni wakati na;

 Jesu, sanu fun wa.


21. Ki iku at’ iye Re,

 Mu ore-ofe ba wa,

 Ti yio mu wa d’ oke:

 Jesu, sanu fun wa. Amin.Yoruba Hymn  APA 212 - Wo t’ o mbebe f’ ota Re

This is Yoruba Anglican hymns, APA 212- Wo t’ o mbebe f’ ota Re   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post