Yoruba Hymn APA 248 - O ti lo. Awosanma

Yoruba Hymn APA 248 - O ti lo. Awosanma

Yoruba Hymn  APA 248 - O ti lo. Awosanma

APA 248

 1. O ti lo. Awosanma,

 Ti gba kuro loju wa,

 Soke orun nibiti

 Oju wa ko le tele;

 O ti kuro l’aiye yi,

 O ti de ibi mimo,

 Lala at’ irora tan,

 Ija tan, o ti segun.


2. O ti lo. Awa si wa

 L’aiye ese at’ iku;

 A ni ’se lati se fun,

 L’aiye t’o ti fisile;

 K’a si tele tokantokan,

 K’a s’ota Re di ore,

 K’a fi Kris than n’iwa wa.


3. O ti lo. On ti wipe,

 “O dara ki Emi lo,”

 Ni ara sa l’o ya wa,

 Sugbon or’ofe Re wa:

 On ni awa ko ri mo,

 A ni Olutunu re,

 Emi Re si je tiwa,

 O ns’ agbara wa d’otun.


4. O ti lo. L’ona kanna,

 L’o ye k’ Ijo Re ma lo;

 K’a gbagbe ohun ehin,

 K’a si ma te siwaju:

 Oro Re ni ’mole wa,

 Titi de opin aiye,

 Nibiti oto Re wa,

 Y’o pese fun alaini.


5. O ti lo. Lekan si i

 A o tun f’ oju wa ri;

 O wa bakanna l’orun,

 Gege b’o ti wa l’aiye:

 N’nu ’bugbe t’o wa nibe,

 Y’o pese aye fun wa,

 Ninu aiye ti mbo wa,

 A o j’okan pelu Re.


6. O ti lo. Fun ire wa,

 E je ki a duro de;

 O jinde, ko si nihin,

 O ti goke re orun;

 Je k’a gb’ okan wa soke,

 Sibiti Jesu ti lo,

 Si odo Olorun wa,

 Nibe l’alafia wa. Amin.


Yoruba Hymn  APA 248 - O ti lo. Awosanma

This is Yoruba Anglican hymns, APA 248-   O ti lo. Awosanma   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post