Yoruba Hymn APA 433 - Li oru ibanuje ni
APA 433
1. Li oru ibanuje ni,
T’ agbara isa oku nde,
S’ Omo iyonu Olorun,
Ore ta A fun ota Re.
2. Ki ’waiyaja Re to bere,
O mu akara, O si bu;
Wo ife n’ ise Re gbogbo,
Gb’ oro ore-ofe t’ O so.
3. “Eyi l’ ara t’ a bu f’ ese,
Gba, k’ e si je onje iye;”
O si mu ago, O bu wain,
Eyi majemu eje Mi.
4. O wipe, “S’ eyi tit’ opin,
N’ iranti iku ore nyin;
’Gba t’ e ba pade, ma ranti
Ife Olorun nyin t’ o lo.
5. Jesu, awa nyo s’ ase Re,
Awa f’ iku Re han l’ orin;
K’ Iwo to pada, ao ma je
Onje ale Odagutan. Amin.
Yoruba Hymn APA 433 - Li oru ibanuje ni
This is Yoruba Anglican hymns, APA 433 - Li oru ibanuje ni. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals