Yoruba Hymn APA 487 - Ile-eko ojo ’simi,
APA 487
1. Ile-eko ojo ’simi,
A, mo ti fe o to!
Inu mi dun mo daraya,
Lati yo ayo re.
2. Ile-eko ojo ’simi,
Ore re p’ apoju;
T’ agba t’ ewe wa nkorin re,
A nse aferi re.
3. Ile-eko ojo ’simi,
Jesu l’o ti ko o;
Emi Mimo Olukoni,
L’o si nse ’toju re.
4. Ile-eko ojo ’simi,
Awa ri eri gba,
P’ Olorun Olodumare
F’ ibukun sori re.
5. Ile-eko ojo ’simi,
B’ orun nrann l’ aranju,
Bi ojo su dudu lorun,
Ninu re l’ emi o wa.
6. Ile-eko ojo ’simi,
Mo yo lati ri O,
’Wo y’o ha koja lori mi
Loni, l’ airi ’bukun? Amin.
Yoruba Hymn APA 487 - Ile-eko ojo ’simi,
This is Yoruba Anglican hymns, APA 487- Ile-eko ojo ’simi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals