Yoruba Hymn APA 146 - Jesu, agbara mi

Yoruba Hymn APA 146 - Jesu, agbara mi

Yoruba Hymn  APA 146 -  Jesu, agbara mi

APA 146

 1. Jesu, agbara mi,

 Iwo l’ aniyan mi;

 Emi fi igbagbo woke,

 Iwo l’o ngb’ adura.

 Je ki nduro de O,

Ki nle se ife Re,

 Ki Iwo Olodumare,

 K’o so mi di otun.


2. Fun mi l’ okan ’rele,

 Ti ’ma se ara re;

 Ti ntemole, ti ko nani

 Ikekun Satani;

 Okan t’ ara re mo

 Irora at’ ise;

 T’o nfi suru at’ igboiya

 Ru Agbelebu re.


3. Fun mi l’ eru orun,

 Oju t’o mu hanhan,

 T’ y’o wo O n’gbe’ ese sunmole,

 K’o ri b’ Esu ti nsa.

 Fun mi ni emi ni,

 T’o ti pese tele;

 Emi t’o nduro gangan lai,

 T’o nf’ adura sona.


4. Mo gbekel’ oro Re,

 ’Wo l’o leri fun mi;

 Iranwo at’ igbala mi

 Y’o t’ odo Re wa se.

 Sa je kin le duro,

 K’ ireti mi ma ye,

 Tit’ Iwo o fi m’ okan mi

 Wo ’nu isimi Re. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 146 -  Jesu, agbara mi  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post