Yoruba Hymn APA 313 - Igbagbo mi wo O

Yoruba Hymn APA 313 - Igbagbo mi wo O

 Yoruba Hymn  APA 313 - Igbagbo mi wo O

APA 313

1. Igbagbo mi wo O,

 Iwo Odaguntan,

 Olugbala:

 Jo gbo adura mi,

 M’ ese mi gbogbo lo,

 K’ emi lat’ oni lo

 Si je Tire.


2. Ki ore- ofe Re

 F’ilera f’ okan mi.

 Mu mi tara:

 B’ Iwo ti ku fun mi,

 A! k’ ife mi si O,

 K’ o ma gbona titi;

 B’ina iye.


3. ‘Gba mo nrin l’ okunkun,

 Ninu ibinuje;

 S’ amona mi.

 M’ okunkun lo loni,

 Pa ‘banuje mi re,

 Ki nma sako kuro

 Li odo Re.


4. Gbati aiye ba pin,

 T’ odo tutu iku

 Nsan lori mi;

 Jesu, ninu ife,

 Mu k’ifoiya mi lo,

 Gbe mi d’ oke orun,

 B’okan t’a ra.  Amin.Yoruba Hymn  APA 313 - Igbagbo mi wo O

This is Yoruba Anglican hymns, APA 313-   Igbagbo mi wo O   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post