Yoruba Hymn APA 467 - Nigba kan ni Betlehemu

Yoruba Hymn APA 467 - Nigba kan ni Betlehemu

Yoruba Hymn  APA 467 - Nigba kan ni Betlehemu

APA 467

 1. Nigba kan ni Betlehemu,

Ile kekere kan wa;

Nib’ iya kan te ’mo re si,

Lori ibuje eran:

Maria n’ iya Omo na,

Jesu Krist si l’ Omo na.


2. O t’ orun wa sode aiye,

On l’ Olorun Oluwa;

O f’ ile eran se ile,

’Buje eran dun ’busun.

Lodo awon otosi

Ni Jesu gbe li aiye.


3. Ni gbogbo igba ewe Re,

O ngboran, o si mb’ ola,

O nferan o si nteriba,

Fun iya ti ntoju Re:

O ye ki gbogb’ omode

K’ o se olugboran be.


4. ’Tori On je awose wa,

A ma dagba bi awa,

O kere, ko le da nkan se,

A ma sokun bi awa;

O si le ba wa daro,

O le ba wa yo pelu.


5. Ao f’ oju wa ri nikehin

Ni agbara ife Re,

Nitori Omo rere yi

Ni Oluwa wa lorun, Lowo otun Olorun.

’Gba ’won ’mo Re b’ irawo

Ba wa n’nu aso ala. Amin.Yoruba Hymn  APA 467 - Nigba kan ni Betlehemu

This is Yoruba Anglican hymns, APA 467- Nigba kan ni Betlehemu . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post