Yoruba Hymn APA 473 - Mo fe gbo itan kanna
1. Mo fe gbo itan kanna
T’ awon angeli nso;
Bi Oba Ogo ti wa
Gbe aiye osi yi;
Bi mo tile J’elese,
Mo mo eyi daju,
Pe Oluwa wa gba mi,
’Tori O fe mi be.
2. Mo yo pe Olugbala
Ti je omode ri;
Lati fi ona mimo
Han awon omo Re;
Bi emi ba si tele
Ipase Re nihin,
On ko ni gbagbe mi lai,
’Tori O fe mi be.
3. Ife ati anu Re,
Y’o je orin fun mi;
B’emi ko tile le ri,
Mo mo pe, O ngbo mi;
O si ti se ileri,
Pe, mo le lo korin
Larin awon angeli,
’Tori O fe mi be. Amin.
Yoruba Hymn APA 473 - Mo fe gbo itan kanna
This is Yoruba Anglican hymns, APA 470- Gba Jesu wo tempili lo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals