Yoruba Hymn APA 475 - Olorun, ran imole Re

Yoruba Hymn APA 475 - Olorun, ran imole Re

  Yoruba Hymn  APA 475 - Olorun, ran imole Re

APA 475

1. Olorun, ran imole Re,

 Si awa omo Re;

 K’ awa le sin k’ a si fe O

 Lat’ ewe tit’ opin.


2. Awa dese, a si foju,

 A nrin l’ ona ’parun;

 L’ okan, ati n’ iwa l’ a fi

 Je ota Olorun.
Yoruba Hymn  APA 475 - Olorun, ran imole Re

This is Yoruba Anglican hymns, APA 475- Olorun, ran imole Re . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals


3. Sugbon ore at’ oluto,

 Nwon nko wa n’ ijanu;

 Nwon nko wa, k’ a wa oju Re,

 T’ a ko le wa l’ asan.


4. A gb’ oju wa s’ ori oke,

 Nibi ’gbala ti nwa;

 ’Wo Orun Ododo, dide,

 Lati m’ ara wa ya.


5. Dide, ran s’ aiye osi yi,

 Ma ran titi aiye!

 Titi awa o fi dagba,

 Ma f’ ona Kristian han. Amin.

[12:31 AM, 1/17/2022] Kosisochukwu: 1. ’Gbati Samuel ji

 T’ o gb’ ohun Eleda

 Ni gbolohun kokan,

 Ayo re tip o to!

 Ibukun ni f’ omo t’ o ri

 Olorun nitosi re be.


2. B’ Olorun ba pe mi

 Pe, ore mi li On,

 Ayo mi y’o ti to!

 Ngo si f’ eti sile,

 Ngo sa f’ ese t’o kere ju,

 B’ Olorun sunmo ’tosi be.


3. Ko ha mba ni soro?

 Beni; n’nu Oro Re

 O npe mi lati wa

 Olorun Samuel;

 N’nu Iwe na ni mo ka pe

 Olorun Samuel npe mi.


4. Mo le f’ ori pamo

 S’ abe itoju Re,

 Mo mo p’ Olorun mbe

 Lodo mi n’gbagbogbo;

 O ye k’ eru ese ba mi,

 ’Tor’ Olorun sunmo ’tosi.


5. ’Gba mba nka oro Re,

 Ki nwi bi Samuel pe:

 Ma wi, Oluwa mi

 Emi y’o gbo Tire;

 ’Gba mo ba si wa n’ ile Re,

 “Ma wi, ’tori ’ranse Re ngbo.” Amin

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post