Yoruba Hymn APA 478 - Ona kan l’o ntoka sorun

Yoruba Hymn APA 478 - Ona kan l’o ntoka sorun

Yoruba Hymn  APA 478 - Ona kan l’o ntoka sorun

APA 478

 1. Ona kan l’o ntoka sorun,

 Isina ni ’yoku;

 Hiha si l’ oju ona na,

 Awon Kristian l’o fe.


2. Lat’ aiye, o lo tarata,

 O si la ewu lo;

 Awon ti nf’ igboya rin I,

 Y’o d’ orun nikehin.


3. Awon ewe y’o ha ti se

 Le la ewu yi ja?

 ’Tori idekun po lona

 F’ awon odomode!


4. Gbigboro lona t’ opo nrin,

 O si teju pelu!

 Mo si mo pe lati dese

 Ni nwon se nrin nibe.


5. Sugbon k’ ese mi ma ba ye,

 Ki nma si sako lo,

 Oluwa, jo s’ oluto mi,

 Emi ki o sina.


6. Nje mo le lo l’ ais’ ifoya,

 Ki ngbekel’ oro Re;

 Apa Re y’o s’ agutan Re,

 Y’o si ko won de ’le.


7. Benin go la ewu yi ja

 Nipa itoju Re;

 Ngo tejumo ’bode orun

 Titi ngo fi wole. Amin.Yoruba Hymn  APA 478 - Ona kan l’o ntoka sorun

This is Yoruba Anglican hymns, APA 478- Ona kan l’o ntoka sorun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post