Yoruba Hymn APA 520 - Awon mimo, lala pari

Yoruba Hymn APA 520 - Awon mimo, lala pari

 Yoruba Hymn  APA 520 - Awon mimo, lala pari

APA 520

1. Awon mimo, lala pari,

 Nwon ti ja, nwon si ti segun,

 Nwon ko fe ohun ija mo,

 Nwon da won ’le l’ ese Jesu:

 A! enyin eni ibukun,

 Isimi nyin ti daju to!


2. Awon mimo, irin pari,

 Nwon ko tun sure ije mo,

 Are at’ isubu d’ opin,

 Ota on eru ko si mo:

 A! enyin eni ibukun,

 Isimi yin ha ti dun to!


3. Awon mimo, ajo pari,

 Nwon ti gun s’ ile ibukun,

 Iji ko deruba won mo,

 Igbi omi ko n’ ipa mo;

 A! enyin eni ibukun,

 E nsimi n’ ib’ alafia.


4. Awon mimo, oku won sun

 Ninu ile, awon nsona

 Titi nwon yio fi jinde,

 Lati fi ayo goke lo:

 A! eni ’bukun, e korin;

 Oluwa at’ Oba nyin mbo.


5. Olorun won, ’Wo l’a nkepe,

 Jesu, bebe fun wa l’ oke;

 Emi Mimo, Oluto wa,

 F’ ore-ofe fun wa d’ opin;

 K’a le b’ awon mimo simi,

 Ni Paradise pelu Re. Amin.Yoruba Hymn  APA 520 - Awon mimo, lala pari

This is Yoruba Anglican hymns, APA 520- Olorun, Awon mimo, lala pari. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post