Yoruba Hymn APA 529 - Jesu Oluwa ni ’se

Yoruba Hymn APA 529 - Jesu Oluwa ni ’se

 Yoruba Hymn  APA 529 - Jesu Oluwa ni ’se

APA 529

1. Jesu Oluwa ni ’se

 Ipile Ijo Re;

 Omi ati oro Re,

 Ni On si fit un da;

 O t’ orun wa, O fi se

 Iyawo mimo Re;

 Eje Re l’O si fir a,

 Ti O si ku fun u.


2. N’ ile gbogbo l’a sa won,

 Sugbon nwon je okan;

 Oluwa kan, ’gbagbo kan,

 Ati baptisi kan;

 Oruko kan ni nwon nyin,

 Onje kan ni nwon nje;

 Opin kan ni nwon nlepa,

 Nipa ore-ofe.


3. Bi aiye tile nkegan,

 gbat’ iyonu de ba;

 B’ija on eko-ke-ko

 Ba mu iyapa wa;

 Awon mimo y’o ma ke

 Wipe, “Y’ o tip e to?”

 Oru ekun fere di

 Oro orin ayo.


4. L’ arin gbogbo ’banuje,

 At’ iyonu aiye,

 O nreti ojo ’kehin

 Alafia lailai;

 Titi y’o f’ oju re ri,

 Iran ologo na,

 Ti ijo nla asegun,

 Y’o d’ ijo ti nsimi.


5. L’aiye, yi o ni ’dapo

 Pelu Metalokan!

 O si ni ’dapo didun

 Pel’ awon t’o ti sun;

 A! alabukun mimo!

 Oluwa, fi fun wa,

 K’ a ba le ri bi awon,

 K’ a ba O gbe l’orun. Amin.Yoruba Hymn  APA 529 - Jesu Oluwa ni ’se

This is Yoruba Anglican hymns, APA 529- Jesu Oluwa ni ’se. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post