Yoruba Hymn APA 544 - Wa, iwo Isun ibukun

Yoruba Hymn APA 544 - Wa, iwo Isun ibukun

Yoruba Hymn  APA 544 - Wa, iwo Isun ibukun

APA 544

 1. Wa, iwo Isun ibukun,

 Mu mi korin ore Re:

 Odo anu ti nsan titi

 Bere orin ’yin kikan.

 Oluwa, ko mi l’orin na,

 T’ ogun orun nko loke;

 Je ki nrohin isura na,

 Ti ife Olorun mi.


2. Nihin l’a ran mi lowo de,

 Mo gbe Ebenesar ro,

 Mo nreti nipa ’nu’re Re,

 Ki nde ’le l’alafia.

 L’ alejo ni Jesu wa mi,

 ’Gba mo sako lo l’ agbo,

 Lati yo mi ninu egbe,

 O f’ eje Re s’ etutu.


3. Nit’ or-ofe, lojojumo

 Ni ’gbese mi si npo si;

 K’ ore-ofe yi ja ewon

 Ti nse ’dena okan mi.

 Ki nsako sa l’ okan mi nfe,

 Ki nko Jesu ti mo fe:

 Olugbala, gba aiya mi,

 Mu ye f’ agbala orun. Amin.



Yoruba Hymn  APA 544 - Wa, iwo Isun ibukun

This is Yoruba Anglican hymns, APA 544-  Wa, iwo Isun ibukun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post