Yoruba Hymn APA 88 - Lehin odun die

Yoruba Hymn APA 88 - Lehin odun die

Yoruba Hymn  APA 88 - Lehin odun die

APA 88

 1. Lehin odun die,

 Lehin igba die,

 A o ko wa jo pel’ awon

 Ti o sun n’ iboji.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo nlanla na !

 Jo, we mi ninu eje Re,

 Si ko ese mi lo.


2. Lehin ojo die

 Laiye buburu yi,

 A o de ’b’ orun ko si mo;

 Ile daradara.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo didan na ! &c


3. Lehin igbi die

 L’ ebute lile yi,

 A o de ’bi’ iji ko si mo,

 T’ okun ki bu soke.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo tutu na ! &c.


4. Lehin ’yonu die

 Lehin ’pinya die,

 Lehin ekun ati aro,

 A ki o sokun mo.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo ’bukun na ! &c.


5. Ojo ’simi die

 L’a ni tun ri laiye ;

 A o de ibi isimi

 Ti ki o pin lailai.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo didun na ! &c.


6. Ojo die l’ o ku,

 On o tun pada wa;

 Enit’ o ku k’ awa le ye,

 K’a ba le ba joba.

 Oluwa, mu mi ye

 Fun ojo ayo na ! Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 88 -  Lehin odun die. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post