Yoruba Hymn APA 89 - Igba mi mbe li owo Re
APA 89
1. Igba mi mbe li owo Re,
A fe k’ o wa nibe;
A f’ ara wa at’ ore wa
Si abe iso Re.
2. Igba mi mbe li owo Re,
Awa o se beru ?
Baba ki y’o je k’ omo Re,
Sokun li ainidi.
3. Igba mi mbe li owo Re,
’Wo l’ a o gbekele;
Tit’ a o f’ aiye osi ’le
T’ a o si r’ ogo Re.
4. Igba mi mbe li owo Re,
Jesu t’ agbelebu;
Owo na t’ ese mi dalu,
Wa di alabo mi.
5. Igba mi mbe li owo Re;
Ngo ma simi le O,
Lehin iku, l’ ow’ otun Re,
L’ em’ o wa titi lai. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 89 - Igba mi mbe li owo Re. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.