Yoruba Hymn APA 34 - Eyi l’ ojo t’ Oluwa da
APA 34
1. Eyi l’ ojo t’ Oluwa da,
O pe ‘gba na ntire:
K’ orun k’ o yo, k’ aiye k’ o yo,
K’ iyin yi ‘te na ka.
2. Loni, o jinde ‘nu oku,
Ijoba Satan tu:
‘Won mimo tan segun RE ka
Nwon nsoro ‘yanu Re.
3. Hosanna si Oba t’ a yan,
S’ Omo mimo Dafid’;
Oluwa, jo sokale wa
T’ Iwo t’ igbala Re.
4. Abukun l’ Oluwa t’ o wa
N’ ise ore-ofe;
T’ o wa l’ oruko Baba re,
Lati gba ‘ran wa la.
5. Hosanna li ohun goro,
L’ orin Ijo t’ aiye,
Orin t’ oke orun lohun
Yio dun ju be lo. Amin.
Yoruba Hymn 34 APA - Eyi l’ ojo t’ Oluwa da
This is Yoruba Anglican hymns, APA 34- Eyi l’ ojo t’ Oluwa da. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.