Yoruba Hymn APA 43 - Yin Olorun, yin lailai

Yoruba Hymn APA 43 - Yin Olorun, yin lailai

Yoruba Hymn  APA 43 - Yin Olorun, yin lailai

APA 43

1. Yin Olorun, yin lailai,

 Fun ife ojojumo;

 Orisun ayo gbogbo,

 K’ iyin Re gb’ enu wa kan.


2. Fun ire t’ oko nmu wa;

 Fun onje t’ a nmu l’ ogba;

 Fun eso igi pelu;

 At’ ororo ti a nlo.


3. Fun gbogb’ eran osin wa

 T’ on siri oka gbigbo;

 Orun tin se ’ri sile;

 Orun ti nm’ oru re wa.


4. Gbogbo nkan t’ erun nmu wa

 Kakiri gbogbo ile;

 At’ eso igba ojo

 Lat’ inu ekun re wa.


5. ’Wo l’ elebun gbogbo won

 Orisun ibukun wa;

 ’Torina okan wa y’o

 F’ iyin at’ ope fun O.


6. Iji lile iba ja

 K’o ba gbogbo oka je:

 K’ eso igi wo danu

 Ki akoko re to pe;


7. Ajara ’ba ma so mo,

 Ki igi gbogbo sig be,

 K’ eran osin gbogbo ku

 K’ eran igbe tan pelu;

 

8. Sibe, Iwo l’ okan wa

 Y’o f’ iyin at’ ope fun;

 Gbat’ ibukun gbogbo tan

 Ao sa fe O fun ’ra Re. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 43 - Yin Olorun, yin lailai. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.


Post a Comment (0)
Previous Post Next Post