Yoruba Hymn APA 73 - Ojo dajo, ojo eru

Yoruba Hymn APA 73 - Ojo dajo, ojo eru

Yoruba Hymn  APA 73- Ojo dajo, ojo eru

APA 73

1. Ojo dajo, ojo eru!

 Gbo bi ipe tin dun to!

 O ju egbarun ara lo,

 O sin mi gbogbo aiye.

 Bi esun na

 Y’o ti damu elese!


2. Wo Onidajo l’awo wa,

 T‘o woo go nla l’aso

 Gbogbo won ti nwo ona Re,

 ’Gbana ni nwon o ma yo.

 Olugbala,

 Jewo mi ni ijo na.


3. Ni pipe Re oku o ji

 Lat’ okun, ile, s’ iye:

 Gbogbo ipa aiye y’o mi,

 Nwon o salo loju Re.

 Alaironu,

 Yio ha ti ri fun o?


4. Esu tin tan o nisiyi,

 iwo ma se gbo tire,

 ’Gbati oro yi koja tan,

 Y’ o ri o ninu ina;

 Iwo ronu

 Ipo re ninu ina !


5. Labe iponju, at’ egan,

 K’ eyi gba o n’ iyanju;

 Ojo Olorun mbo tete,

 ’Gbana ekun y’o d’ ayo,

 A o segun

 Gbati aiye ba gbina. Amin.

Yoruba Hymn  APA 73- Ojo dajo, ojo eru

This is Yoruba Anglican hymns, APA 73 - Ojo dajo, ojo eru. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.


Post a Comment (0)
Previous Post Next Post