Yoruba Hymn APA 78 - Onigbagbo, e bu s’ ayo

Yoruba Hymn APA 78 - Onigbagbo, e bu s’ ayo

Yoruba Hymn  APA 78-  Onigbagbo, e bu s’ ayo

APA 78

 1. Onigbagbo, e bu s’ ayo,

 Ojo nla l’ eyi fun wa;

 E gbo bi awon Angeli

 Ti nf’ ogo fun Olorun:

 Alafia, Alafia

 Ni fun gbogbo enia .


2. Ki gbogbo aiye ho f’ ayo,

 K’ a f’ ogo fun Olorun,

 Omo bibi Re l’ o fun wa

 T’ a bi ninu Wundia:

 En’ Iyanu, En’ Iyanu

 Ni Omo t’ a bi loni.


3. Ninu gbogbo rudurudu,

 On ibi t’ o kun aiye,

 Ninu idamu nla ese

 L’ Om’ Olorun wa gba wa:

 Olugbimo, Olugbimo,

 Alade Alafia.


4. Olorun Olodumare

 L’ a bi, bi omo titun:

 Baba ! Eni aiyeraiye

 L’ o di alakoso wa:

 E bu s’ ayo, E bu s’ ayo,

 Omo Dafidi joba.

 

5. O wa gba wa lowo ese,

 O wa d’ onigbowo wa

 Lati fo itegun Esu

 A se ni Oba Ogo:

 E ku ayo, E ku ayo,

 A gba wa lowo iku. Amin.

Yoruba Hymn  APA 78-  Onigbagbo, e bu s’ ayo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 78 - Onigbagbo, e bu s’ ayo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post