Yoruba Hymn APA 77- Eyin Angel l’ orun ogo
APA 77
1. Eyin Angel l’ orun ogo,
To yi gbogbo aiye ka;
E ti korin dida aiye,
E so t’ ibi Messia;
E wa josin, E wa josin,
Fun Kristi Oba titun.
2. Enyin Oluso-agutan,
Ti nso eran nyin loru,
Emanueli wa ti de,
Irawo omo na ntan;
E wa josin, &c.
3. Onigbagbo ti nteriba,
Ni ’beru at’ ireti
L’ ojiji l’ Oluwa o de
Ti yio mu nyin re ’le.
E wa josin, &c.
4. Elese ’wo alaironu
Elebi ati egbe
Ododo Olorun duro,
Anu npe o, pa ’wa da;
Sa wa josin, &c.
5. Gbogbo eda e fo f’ ayo,
Jesu Olugbala de.
Anfani miran ko si mo
B’ eyi ba fo nyin koja;
Nje, e wa sin, Nje, e wa sin,
Sin Kristi Oba Ogo. Amin.
Yoruba Hymn APA 77- Eyin Angel l’ orun ogo
This is Yoruba Anglican hymns, APA 77 - Eyin Angel l’ orun ogo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.