Yoruba Hymn APA 233 - Mo wi fun olukuluku

Yoruba Hymn APA 233 - Mo wi fun olukuluku

 Yoruba Hymn  APA 233 - Mo wi fun olukuluku

APA 233

1. Mo wi fun olukuluku

 Pe, On ji, O si ye;

 O si wa larin wa pelu,

 Nipa Emi iye.


2. E wi fun enikeji nyin,

 Kin won ji pelu wa,

 K’ imole k’ o wa kakiri

 Ni gbogbo aiye wa.


3. Nisisiyi aiye yi ri

 Bi ile Baba wa:

 Iye titun ti On fun ni,

 O so d’ ile Baba.


4. Ona okun ti On ti rin

 Mu ni lo si orun;

 Enit o rin bi On ti rin,

 Y’o d’ odo Re l’ orun.


5. On ye, O si wa pelu wa,

 Ni gbogbo aiye yi;

 Ati nigbat’ a f’ ara wa,

 F’ erupe ni ’reti. Amin.


 Yoruba Hymn  APA 233 - Mo wi fun olukulukuPost a Comment (0)
Previous Post Next Post