Yoruba Hymn APA 239 - Kini ’simi ayo ailopin ni

Yoruba Hymn APA 239 - Kini ’simi ayo ailopin ni

Yoruba Hymn  APA 239 - Kini ’simi ayo ailopin ni

APA 239

 1. Kini ’simi ayo ailopin ni,

 T’ awon angel at’ awon mimo ni?

 ’Simi f’ alare; f’ awon asegun,

 Nibe l’ Olorun je ohun gbogbo.


2. ’Tal’ Oba na? tani yi ’te Re ka?

 Irora itura Re ha ti ri?

 So funni, enyin ti njosin nibe:

 So funni, b’ oro to t’ayo nyin so.


3. Jerusalem toto, ilu mimo,

 Alafia eyit’ o je kik’ ayo;

 A r’ ohun t’a nfe n’nu re k’a to wi,

 A si rigba ju eyit’ a nfe lo.


4. L’ agbala Oba wa, wahala tan,

 Laiberu l’a o ma korin Sion;

 Oluwa, niwaju Re lao ma fi

 Idahun ’fe han f’ ebun ife Re.


5. ’Simi ko le tele ’Simi nibe:

 Enikan ni ’Simi ti nwoju Re.

 Nibe orin jubeli ko le tan,

 T’ awon mimo at’ angeli y’o ko.


6. L’ aiye yi, pelu ’gbagbo at’ adua,

 L’ ao ma saferi ’le Baba ohun;

 Si Salem l’awon ti a si nipo

 Npada lo; lat’ ilu Babiloni.


7. Nje awa teriba niwaju Re,

 T’ Eniti ohun gbogbo jasi;

 Ninu eniti Baba at’ Omo,

 T’ Eniti Emi je Okanso lai. Amin.Yoruba Hymn  APA 239 - Kini ’simi ayo ailopin ni

This is Yoruba Anglican hymns, APA 239- Kini ’simi ayo ailopin ni   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post