Yoruba Hymn APA 241 - Wo Asegun b’o ti goke

Yoruba Hymn APA 241 - Wo Asegun b’o ti goke

Yoruba Hymn  APA 241 - Wo Asegun b’o ti goke

APA 241

1. Wo Asegun b’o ti goke

 Wo Oba n’nu ola Re,

 O gun keke ofurufu

 Lo sorun agbala Re;

 Gbo orin awon Angeli,

 Halleluya ni nwon nko,

 Awon ’lekun si si sile,

 Lati gba Oba orun.


2. Tani Ologo ti mbo yi,

 T’oni ti ipe jubeli?

 Oluwa awon ’mo-ogun,

 On to ti segun fun wa,

 O jiya lor’ agbelebu,

 O jinde ninu oku,

 O segun Esu at’ ese,

 Ati gbogbo ota Re.


3. B’o ti nbuk’ awon ore Re,

 A gba kuro lowo won;

 Bi oju nwon si ti nwo lo,

 O nu nin’ awosanma;

 Enit’o ba Olorun rin,

 T’o si nwasu otito,

 On, Enoku wa, l’a gbe lo

 S’ile Re loke orun.


4. On, Aaron wa, gbe eje Re

 Wo inu ikele lo,

 Josua wa, ti wo Kenaan,

 Awon oba nwariri;

 A fi ’di eya Israel

 Mule nibi ’simi won;

 Elija wa si fe fun wa

 N’ilopo meji Emi.


5. Iwo ti gbe ara wa wo

 Lo s’ ow’ otun Olorun,

 A si joko nibi giga

 Pelu Re ninu ogo;

 Awon Angeli mbo Jesu,

 Enia joko lor’ ite,

 Oluwa, b’ Iwo ti goke,

 Jo je k’a le goke be. Amin. Yoruba Hymn  APA 241 - Wo Asegun b’o ti goke

This is Yoruba Anglican hymns, APA 241-  Wo Asegun b’o ti goke    . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post