Yoruba Hymn APA 303 - Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa

Yoruba Hymn APA 303 - Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa

Yoruba Hymn  APA 303 - Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa

APA 303

 1. Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa,

 On o si dide fun Igbala mi;

 Ki nsa ma gbadura, On o se ranwo;

 ‘Gba Krist wa lodo mi, ifoiya ko si.


2. B’ona mi ba su, On l’o sa n to mi,

 Ki nsa gboran sa, On o si pese;

 Bi iranlowo eda gbogbo saki,

 Oro t’ enu Re so y’o bori dandan.


3. Ife t’o nfi han ko je ki nro pe,

 Y’o fi mi sile ninu wahala;

 Iranwo ti mo si nri lojojumo,

 O nki mi laiya pe, emi o la ja.


4. Emi o se kun tori iponju,

 Tabi irora? O ti so tele!

 Mo m’ oro Re p’awon ajogun ‘gbala,

 Nwon ko le s’ aikoja larin wahala.


5. Eda ko le so kikoro ago

 T’ Olugbala mu, k’ elese le ye;

 Aiye Re tile buru ju temi lo,

 Jesu ha le jiya, k’ emi si ma sa!


6. Nje b’ ohun gbogbo ti nsise ire,

 Adun n’ ikoro, onje li ogun;

 B’ oni tile koro, sa ko ni pe mo,

 Gbana orin ‘segun yio ti dun to!.Amin.



Yoruba Hymn  APA 303 - Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa

This is Yoruba Anglican hymns, APA 303-  Aigbagbo, bila ! temi l’ Oluwa . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post