Yoruba Hymn APA 302 - Iwo Isun imole

Yoruba Hymn APA 302 - Iwo Isun imole

Yoruba Hymn  APA 302 - Iwo Isun imole

 APA 302

1. Iwo Isun imole;

 Ogo ti ko l’ okunkun;

 Aiyeraiye, titi lai,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


2. Kanga Iye tin san lai;

 Iye ti ko l’ abawon,

 Iye t’ o ni irora,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


3. Olubukun, Olufe,

 Omo Re mbe O loke;

 Emi Re nrado bo wa;

 Baba Mimo, gbo ti wa.


4. Y’ ite safire Re ka

 L’ osumare ogo ntan;

 O kun fun Alafia,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


5. N’ iwaju ’te anu Re

 L’ awon Angeli npade,

 Sugbon wow a lese Re,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


6. Iwo ti okan Re nyo

 S’ amusua t’ o pada,

 T’O mo ’rin re lokere,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


7. Okan ti nwa isimi;

 Okan t’ eru ese npa;

 B’ om’-owo ti nke f’ omu,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


8. Gbogbo wa ni alaini

 L’ ebi, l’ ongbe at’ are;

 Ko si ede f’ aini wa,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


9. Isura opolopo

 Ko l’O kojo bi Oba?

 Ainiye, aidiyele?

 Baba Mimo, gbo ti wa.


10. ’Wo ko da Omo Re si,

 Omo Re kansoso na,

 Tit’ O fi par’ ise Re,

 Baba Mimo, gbo ti wa.


APA II


1. ’Wo t’O sunmo, gb’ O nkedun,

 T’O gbo ’gbe Re ikehin;

 T’O jowo Re lati ku.

 Baba Mimo, gbo ti wa.


2. Iwo ti o le gba ni

 L’owo iji iparun,

 L’owo ’boji at’ iku.

 Baba Mimo, gbo ti wa.


3. ’Wo low’ otun Eniti

 On joko nisisiyi,

 T’O gunwa bi t’ isaju

 Baba Mimo, gbo ti wa.


4. ’Wo t’O f’ ore de l’ade,

 T’O si gbe mo aiya Re,

 On n’ Imole oju Re.

 Baba Mimo, gbo ti wa.


5. Gbogb’ ebun meje orun,

 Lodo Emi meje ni

 A fi won fun l’ ainiwon

 Baba Mimo, gbo ti wa.


6. L’ase Re ni Emi wa,

 ’Mole at’ ela ahon,

 L’oko Olurapada.

 Baba Mimo, gbo ti wa.


7. Fun wa li akoko yi,

 Lat’ inu ebun Re wa,

 ’Mole, iye, agbara.

 Baba Mimo, gbo ti wa.


8. Gbo ’gbe wa, gbo aini wa;

 Gbo, Emi mbebe n’nu wa:

 Gbo, tori Jesu nsipe.

 Baba Mimo, gbo ti wa. Amin.Yoruba Hymn  APA 302 - Iwo Isun imole

This is Yoruba Anglican hymns, APA 302-  Iwo Isun imole . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post