Yoruba Hymn APA 305 - Jesu l’ Olusagutan mi

Yoruba Hymn APA 305 - Jesu l’ Olusagutan mi

Yoruba Hymn  APA 305 - Jesu l’ Olusagutan mi

APA 305

 1. Jesu l’ Olusagutan mi,

 Ore eniti ki ye!

 Ko s’ ewu bi mo je Tire,

 T’ On si je temi titi.


2. Nib’ odo omi iye nsan,

 Nibe l’o nm’ okan mi lo;

 Nibiti oko tutu nhu,

 L’o nf’ onje orun bo mi.


3. Mo ti fi were sako lo,

 N’ ife O si wa miri;

 L’ ejika Re l’o gbe mi si,

 O f’ ayo mu mi wa ‘le.


4. Nko beru ojiji iku,

 B’ Iwo ba wa lodo mi;

 Ogo Re ati opa Re,

 Awon l’o ntu mi ninu.


5. Iwo te tabili fun mi;

 ‘Wo d’ ororo sori mi;

 A! ayo, na ha ti po to!

 Ti nt’ odo Re wa ba mi.


6. Be, lojo aiye mi gbogbo,

 Ore re ki o ye lai:

 Olusagutan, ngo yin O,

 Ninu ile Re titi. Amin.Yoruba Hymn  APA 305 - Jesu l’ Olusagutan mi

This is Yoruba Anglican hymns, APA 305- Jesu l’ Olusagutan mi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post