Yoruba Hymn APA 358 - Nihin mo j’ alejo

Yoruba Hymn APA 358 - Nihin mo j’ alejo

Yoruba Hymn  APA 358 - Nihin mo j’ alejo

APA 358

 1. Nihin mo j’ alejo,

 Orun n’ ile.

 Atipo ni mo nse,

 Orun n’ ile.

 Ewu on banuje

 Wa yi mi kakiri;

 Orun ni ilu mi,

 Orun n’ ile.


2. B’ iji ba tile nja,

 Orun n’ ile:

 Kukuru l’ ajo mi,

 Orun n’ ile.

 Iji lile ti nja,

 Fe rekoja lo na;

 Ngo sa de ’le dandan,

 Orun n’ ile.


3. Lodo Olugbala,

 Orun n’ ile;

 A o se mi logo,

 Orun n’ ile.

 Nib’ awon mimo wa,

 Lehin ’rin-ajo won,

 Ti nwon ni ’simi won,

 Nibe n’ ile.


4. Nje nki o kun, tori

 Orun n’ ile:

 Ohun t’ o wu ki nri,

 Orun n’ ile.

 Ngo sa duro dandan,

 L’ otun Oluwa mi:

 Orun ni ilu mi

 Orun n’ ile. Amin.



Yoruba Hymn  APA 358 - Nihin mo j’ alejo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 358- Nihin mo j’ alejo  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post