Yoruba Hymn APA 403 - Eredi irokeke yi

Yoruba Hymn APA 403 - Eredi irokeke yi

Yoruba Hymn  APA 403 - Eredi irokeke yi

APA 403

 1. Eredi irokeke yi

 Ti enia ti nwo koja?

 ’Jojumo n’ iwojopo na,

 Eredi re ti nwon nse be?

 Nwon dahun lohun jeje pe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”

 Nwon si tun dahun lohun jeje pe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”


2. Tani Jesu? ese ti On

 Fin mi gbogbo ilu bayi?

 Ajeji Ologbon ni bi,

 Ti gbogb’ enia nto lehin?

 Nwon si tun dahun jeje pe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”

 Nwon si tun dahun lohun jeje pe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”


3. Jesu, On na l’O ti koja,

 Ona irora wa laiye;

 ’Bikibi t’ O ba de, nwon nko

 Orisi arun wa ’do Re;

 Afoju yo, b’o ti gbo pe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”

 Afoju yo, b’o ti gbo pw,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”


4. On si tun de! nibikibi

 Ni awa si nri ’pase Re:

 O nrekoja lojude wa

 O wole lati ba wa gbe.

 Ko ha ye k’a f’ ayo ke pe?

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”

 Ko ha ye k’a f’ ayo ke pe?

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”


5. Ha! e wa enyin t’orun nwo!

 Gba ’dariji at’ itunu:

 Enyin ti e ti sako lo,

 Pada, gba or’-ofe Baba;

 Enyin t’a danwo, abo mbe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”

 Enyin t’a danwo, abo mbe,

 “Jesu ti Nasaret’ l’o nkoja.”


6. Sugbon b’ iwo ko ipe yi,

 Ti o sig an ife nla Re,

 On yio kehinda si o,

 Yio si ko adura re;

 “ O pe ju” n’ igbe na y’o je:

 “ Jesu ti Nasaret’ ti koja.”

 “ O pe ju” n’ igbe na y’o je:

 “ Jesu ti Nasaret’ ti koja.” Amin.Yoruba Hymn  APA 403 - Eredi irokeke yi

This is Yoruba Anglican hymns, APA 403-  Eredi irokeke yi . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post