Yoruba Hymn APA 404 - Nigbat’ idanwo yi mi ka

Yoruba Hymn APA 404 - Nigbat’ idanwo yi mi ka

 Yoruba Hymn  APA 404 - Nigbat’ idanwo yi mi ka

APA 404

1. Nigbat’ idanwo yi mi ka,

 Ti idamu aiye mu mi;

 T’ ota f’ ara han bi ore

 Lati wa iparun fun mi;

 Oluwa jo, ma s’ aipe mi

 B’o ti pe Adam nin’ ogba

 Pe, “Nibo l’o wa” elese?

 Ki nle bo ninu ebi na.


2. Nigbat’ Esu n’nu ’tanje re

 Gbe mi gori oke aiye,

 T’o ni ki nteriba fun on,

 K’ ohun aiye le je temi.

 Oluwa jo, &c.


3. ’Gbat’ ogo aiye ba fe fi

 Tulasi mu mi rufin Re;

 T’o duro gangan lehin mi;

 Ni ileri pe, “Ko si nkan.”

 Oluwa jo, &c.


4. Nigbati igbekele mi

 Di t’ ogun ati t’ orisa;

 T’ ogede di adura mi,

 Ti ofo di ajisa mi.

 Oluwa jo, &c.


5. Nigbati mo fe lati rin

 L’ adamo at’ ife ’nu mi,

 T’ okan mi nse hilahilo,

 Ti nko gbona, ti nko tutu.

 Oluwa jo, &c.


6. Nigba mo sonu bi aja,

 L’ aigbo ifere ode mo;

 Ti nko nireti ipada,

 Ti mo npafo ninu ese.

 Oluwa jo, &c.


7. Nigbati ko s’ alabaro;

 Ti olutunu si jina;

 T’ ibinuje, b’ iji lile,

 Te ori mi ba n’ ironu.

 Oluwa jo, ma s’aipe mi

 B’o ti pe Adam nin’ ogba

 Pe, “Nibo l’o wa” elese?

 Kin le bo ninu ebi na. Amin.Yoruba Hymn  APA 404 - Nigbat’ idanwo yi mi ka

This is Yoruba Anglican hymns, APA 404- Nigbat’ idanwo yi mi ka. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post