Yoruba Hymn APA 411 - Wa sodo mi, alare

Yoruba Hymn APA 411 - Wa sodo mi, alare

Yoruba Hymn  APA 411 - Wa sodo mi, alare

APA 411

 1. “Wa sodo mi, alare,

 Ngo fun nyin n’ isimi,”

 A! ohun didun Jesu,

 Ti o p’ elese wa.

 O nso ti ore-ofe,

 Ati t’ alafia,

 Ti ayo ti ko lopin,

 T’ ife ti ko le tan.


2. “E wa, enyin omo Mi,

 Ngo fun nyin n’ imole”

 A! ohun ife Jesu,

 Ti nle okunkun lo;

 Awa kun fun banuje,

 A ti s’ ona wa nu;

 Imole y’o m’ ayo wa,

 Oro y’o m’ orin wa.


3. “E wa, enyin ti ndaku,

 Ngo fun nyin ni iye:”

 Ohun alafia Jesu,

 T’ o f’ opin s’ ija wa.

 Oju ota wa koro,

 Ija si le pupo;

 Sugbon ’Wo fun wa n’ipa,

 A bori ota wa.


4. “Enikeni t’ o ba wa,

 Emi ki o ta nu;”

 A! ohun suru Jesu,

 T’ o le ’yemeji lo!

 Ninu ife iyanu,

 T’o p’ awa elese,

 B’a tile je alaiye,

 S’odo Re, Oluwa. Amin.Yoruba Hymn  APA 411 - Wa sodo mi, alare

This is Yoruba Anglican hymns, APA 411- Wa sodo mi, alare . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post