Yoruba Hymn APA 90 - Apata aiyeraiye

Yoruba Hymn APA 90 - Apata aiyeraiye

Yoruba Hymn  APA 90 - Apata aiyeraiye

APA 90

1. Apata aiyeraiye,

 Enit’ o mbe lailai,

 Nigbakugba t’ iji nja,

 ’Wo ’bugbe Alafia:

 Saju dida aiye yi,

 Iwo mbe; bakanna

 Tit’ aiye ainipekun,

 Aiyeraiye ni ’Wo.


2. Oj’ odun wa ri b’oji

 T’o han l’ori oke;

 Bi koriko ipado,

 T’o ru ti o si ku:

 Bi ala; tabi b’itan,

 T’enikan nyara pa :

 Ogo ti ko ni si mo,

 Ohun t’o gbo tan ni.


3. ’Wo eniti ki togbe,

 ’Mole enit’ itan;

 Ko wa bi a o ti ka

 Ojo wa k’o to tan;

 Je k’anu Re ba le wa,

 K’ Ore Re po fun wa;

 Si je k’ Emi Mimo Re,

 Mole si okan wa.


4. Jesu, f’ewa at’ ore,

 De ’gbagbo wa l’ade;

 Tit’ ao fi ri O gbangba,

 Ninu ’mole lailai;

 Ayo t’enu ko le so,

 Orisun akunya,

 Alafia ailopin,

 Okun ailebute. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 90 - Apata aiyeraiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post