Yoruba Hymn APA 25 - Ojo ‘simi at’ ayo
APA 25
1. Ojo ‘simi at’ ayo,
Ojo inu didun,
Ogun fun ibanuje
Ojo dida julo;
Ti awon eni giga
Niwaju ite Re
Nko mimo, mimo, mimo,
S’eni Metalokan.
2. L’ ojo yi ni ‘mole la,
Nigba dida aiye:
Ati fun igbala wa
Krisit jinde loni:
L’ ojo oni l’ Oluwa,
Ran emi t’ orn wa;
Ojo ologo julo
T’ o ni ‘mole pipe.
3. Orisun ‘tura ni O,
Laiye aginju yi:
L’ ori Re, bi ni Pisga
L’ a nwo ‘le ileri.
Ojo ironu didun
Ojo ife mimo,
Ojo ajinde, lati
Aiye, si nkan orun.
4. L’ oni s’ ilu t’ are mu
Ni Manna t’ orun bo;
Si ipejopo mimo
N’ ipe fadaka ndun.
Nibiti Ihin – rere
Ntan imole mimo,
Omi iye nsan jeje
Ti ntu okan lara.
5. K’ a r’ ore-ofe titun
L’ ojo ‘simi wa yi,
K’ a side ‘simi t’ o ku
F’ awon alabukun.
Nibe k’ a gbohun soke
Si Baba at’ Omo
Ati si Emi Mimo,
N’ iyin Metalokan. Amin.
Yoruba Hymn APA 25 - Ojo ‘simi at’ ayo
This is Yoruba Anglican hymns, APA 25 - Ojo ‘simi at’ ayo. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.