Yoruba Hymn APA 27 - Ojo isimi Olorun
APA 27
1. Ojo isimi Olorun,
Ojo ti o dara julo;
Ti Olorun ti fi fun wa,
K’ awa k’o simi ninu re.
2. Ijo mefa l’O fifun wa,
K’a fi se ise wa gbogbo;
Sugbon ojo keje yato,
Ojo ’simi Olorun ni.
3. K’a fi ’se asan wa sile,
Ti awa nse n’ ijo mefa;
Mimo ni ise ti oni,
Ti Olorun Oluwa wa.
4. A para de nisisiyi
Ninu ile Olorun wa;
Jek’ a korin didun si I,
Li owuro ojo oni.
5. Ni kutukutu ’jo keje
Ni ojo isimi mimo
Je k’ a jumo korin didun,
Je k’ a si jumo gbadura. Amin.
Yoruba Hymn APA 27 - Ojo isimi Olorun
This is Yoruba Anglican hymns, APA 27 - Ojo isimi Olorun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.