Yoruba Hymn APA 49 - Iwo mbo wa, Oluwa mi

Yoruba Hymn APA 49 - Iwo mbo wa, Oluwa mi

 Yoruba Hymn APA 49 - Iwo mbo wa, Oluwa mi

APA 49

 1. Iwo mbo wa, Oluwa mi,

 Iwo mbo wa, Oba mi,

 Ninu itansan ewa Re;

 Ninu titayo ogo Re;

 O ye k’a yo, k’a korin !

 O mbo :-- ni ila-orun

 Awon akede npo si;

 O mbo :-- Alufa ogo;

 A ko ha ngbo ago Re?


2. Iwo mbo wa, Iwo mbo wa

 A o pade Re lona;

 A o ri O, a o mo O:

 A o yin O; gbogbo okan

 L’a o sipaya fun O:

 Orin kil’ eyi o je !

 Orin t’o dun rekoja:

 A o tu ’fe wa jade

 Si ese Re Ologo.


3. Iwo mbo wa; ni tabil’ Re,

 L’ awa njeri si eyi;

 T’a mo p’ O npade okan wa

 Ni idapo mimo julo;

 Eri ibukun ti mbo,

 Ko f’ iku Re nikan han,

 At’ ife titobi Re,

 Sugbon bibo Re pelu

 T’a nfe, t’a si nduro de.

 

4. Y’o dun lati ri O njoba

 Oluwa mi Olufe;

 Ki gbogbo ahon jewo Re;

 Iyin, ola, ati ogo,

 Kin won jumo fi fun O:

 ’Wo, Oga mi, Ore, mi,

 K’o segun, k’ o si gunwa,

 Titi de opin aiye,

 Ninu ogo at’ ola. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 49 - Iwo mbo wa, Oluwa mi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.


Post a Comment (0)
Previous Post Next Post