Yoruba Hymn APA 54 - Gbo ohun olore

Yoruba Hymn APA 54 - Gbo ohun olore

Yoruba Hymn  APA  54- Gbo ohun olore

APA 54

1. Gbo ohun olore,

 Ji, ara, ji:

 Jesu ma fere de,

 Ji, ara, ji,

 Omo oru ni ’sun,

 Omo imole l’enyin,

 Ti nyin l’ogo didan,

 Ji, ara, ji.


2. So f’egbe t’ o ti ji,

 Ara, sora;

 Ase Jesu daju

 Ara , sora;

 E se b’olusona

 N’ ilekun Oluwa nyin,

 Bi o tile pe de,

 Ara, sora


3. Gbo ohun Iriju,

 Ara, sise;

 Ise na kari wa,

 Ara, sise;

 Ogba Oluwa wa,

 Kun fun ’se nigbagbogbo;

 Y’o si fun wa l’ere,

 Ara, sise.


4. Gb’ ohun Oluwa wa,

 E gbadura;

 B’ e fe k’inu Re dun,

 E gbadura;

 Ese mu ’beru wa,

 Alailera si ni wa;

 Ni ijakadi nyin,

 E gbadura.

 

5. Ko orin ikehin,

 Yin, ara, yin;

 Mimo ni Oluwa,

 Yin, ara, yin;

 Kil’ o tun ye ahon,

 T’o fere b’angel korin,

 T’ y’o ro l’orun titi,

 Yin, ara, yin. Amin.

This is Yoruba Anglican hymns, APA 54 - Gbo ohun olore. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.


Post a Comment (0)
Previous Post Next Post