Yoruba Hymn APA 71 - Olorun ! kini mo ri yi
APA 71
1. Olorun ! kini mo ri yi !
Opin de f’ ohun gbogbo !
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ ite ’dajo.
Ipe dun, iboji sit u
Gbogbo awon oku sile:
Mura, lo ko, okan mi.
2. Oku ’nu Krist y’o ko jinde,
Nigba ’pe kehin ba dun;
Nwon o lo ko l’ awosanma,
Nwon o fi ayo yi ka:
Ko s’ eru ti y’o b’ okan won;
Oju Re da imole bo,
Awon ti o mura de.
3. Sugbon elese t’ on t’ eru !
Ni gbigbona ’binu Re,
Nwon o dide, nwon o si ri,
Pe, ose won ko ba mo;
Ojo ore-ofe koja;
Nwon ngbon niwaju ’te ’dajo,
Awon ti ko mura de.
4. Olorun kini mo ri yi;
Opin de f’ ohun gbogbo !
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ ite ’dajo.
L’ese agbelebu, mo nwo
’Gbat’ ohun gbogbo y’ o koja;
Bayi ni mo nmura de. Amin.
Yoruba Hymn APA 71 - Olorun ! kini mo ri yi
This is Yoruba Anglican hymns, APA 71 - Olorun ! kini mo ri yi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.