Yoruba Hymn APA 110 - Enyin enia Olorun
APA 110
1. Enyin enia Olorun,
Okunkun yi aiye ka;
So ihin ayo ti Jesu
Ni gbogb’ orile-ede;
Ihin ayo, Ihin ayo
Ti ’toye Olugbala.
2. Ma tiju Ihinrere Re,
Agbara Olorun ni.
N’ ilu t’ a ko wasu Jesu,
Kede ’dasile f’ onde;
Idasile, Idasile
Bi t’ awon omo Sion.
3. B’ aiye on Esu dimolu
S’ ise Olugbala wa,
Ja fun ise Re, ma foya,
Mase beru enia.
Nwon nse lasan, Nwon nse lasan,
Ise Re ko le baje.
4. ’Gbat’ ewu nla ba de sin yin;
Jesu y’o dabobo nyin;
Larin ota at’ alejo,
Jesu y’o je Ore nyin;
Itoju Re, Itoju Re
Y’o pelu nyin tit’ opin. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 110 - Enyin enia Olorun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.