Yoruba Hymn APA 228 - Halleluya, Halleluya

Yoruba Hymn APA 228 - Halleluya, Halleluya

 Yoruba Hymn  APA 228 - Halleluya, Halleluya

APA 228

1. Halleluya, Halleluya,

 E gbe ohun ayo ga,

 E ko orin inudidun,

 K’e si yin Olorun wa!

 Enit’a kan m’agbelebu,

 T’o jiya fun ese wa;

 Jesu Kristi Oba ogo

 Jinde kuro n’nu oku.


2. Irin idabu se kuro,

 Kristi ku o sit un ye,

 O mu iye ati aiku

 Wa l’oro ajinde Re.

 Kristi ti segun, awa segun

 Nipa agbara nla Re,

 Awa o jinde pelu Re,

 A o ba wo’nu Ogo.


3. Kristi jinde, akobi ni

 Ninu awon t’o ti sun,

 Awon yi ni y’o ji dide,

 Ni abo Re ekeji;

 Ikore ti won tip on tan,

 Nwon nreti Olukore,

 Eniti y’o mu won kuro,

 Ninu isa oku won.


4. Awa jinde pelu Kristi,

 To nfun wa l’ohun gbogbo,

 Ojo, iri, ati ogo

 To ntan jade loju Re,

 Oluwa, b’ a ti wa l’aiye,

 Fa okan wa sodo Re,

 K’awon angeli sa wa jo,

 Kin won ko wa d’odo Re.


5. Halleluya, Halleluya!

 Ogo ni fun Olorun;

 Halleluya f’ Olugbala,

 Enit’o segun iku;

 Halleluya f’ Emi Mimo,

 Orisun ’fe, ’wa mimo,

 Halleluya, Halleluya,

 F’Olorun Metalokan. Amin.


Yoruba Hymn  APA 228 - Halleluya, Halleluya

This is Yoruba Anglican hymns, APA 228- Halleluya, Halleluya  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post