Yoruba Hymn APA 258 - Lehin aiye okunkun yi

Yoruba Hymn APA 258 - Lehin aiye okunkun yi

Yoruba Hymn  APA 258 - Lehin aiye okunkun yi

APA 258

 1. Lehin aiye okunkun yi,

 Ogo ailopin mbe;

 At’ ilu ayo ti ki tan,

 T’ oju eda ko ri.


2. Ilu ewa! oju wa ’ba

 Ri ’daji ayo re,

 Okan wa iba ti fe to

 Lati f’ aiye sile!


3. Aisan on ’rora ki de ’be,

 Ibanuje ko si;

 Ilera ni lojo gbogbo,

 Adun ti ko lopin.


4. Oru ko si n’ ilu wonni,

 Osan ni titi lai;

 Ese, orison egbe wa,

 Ko le wo ’be titi.


5. A! k’ ireti orun wa yi

 Mu okan wa gbona,

 K’ igbagbo at’ ife nla yi

 M’ ero wa lo soke.


6. Oluwa, ’lanu se wa ye

 Fun agbala orun;

 Si so f’ okan wa k’o dide

 Dapo m’ awon t’ orun. Amin.


Yoruba Hymn  APA 258 - Lehin aiye okunkun yi


This is Yoruba Anglican hymns, APA 259- Lehin aiye okunkun yi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post