Yoruba Hymn APA 257 - Oke kan mbe t’ o ga

Yoruba Hymn APA 257 - Oke kan mbe t’ o ga

Yoruba Hymn  APA 257 -  Oke kan mbe t’ o ga

APA 257

1. Oke kan mbe t’ o ga,

 Nibi t’ a m’ Olorun;

 O wa l’ okere ni orun;

 Ite Olorun ni.


2. Tal’ awon t’ o sunmo ibe,

 Lati wo ite Re?

 Egbarun won t’ o wa nibe,

 Omode bi awa.


3. Olugbala w’ ese won nu,

 O so won di mimo;

 Nwon f’ oro Re, nwon f’ ojo Re,

 Nwon fe, nwon si ri i.


4. Labe opo oko tutu,

 L’ara won simi si:

 Nwon ri ’gbala okan won he,

 Laiya Olugbala.


5. K’ awa k’ o rin bi nwon ti rin,

 Ipa t’ o lo s’ orun;

 Wa idariji Olorun,

 T’ o ti dariji won.


6. Jesu ngbo irele ekun,

 T’ o mu okan d’ otun;

 Lori oke t’ o ndan, t’ o ga,

 L’awa o ma wo O. Amin. Yoruba Hymn  APA 257 -  Oke kan mbe t’ o ga

This is Yoruba Anglican hymns, APA 257 -  Oke kan mbe t’ o ga . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post