Yoruba Hymn APA 264 - Olurapada wa, k’On to

Yoruba Hymn APA 264 - Olurapada wa, k’On to

Yoruba Hymn  APA 264 - Olurapada wa, k’On to

APA 264

 1. Olurapada wa, k’On to

 Dagbere ikehin,

 O fi Olutunu fun ni,

 Ti mba wa gbe.


2. O wa ni awo adaba

 O na iye bo wa;

 O tan ’fe on alafia

 Sori aiye.


3. O de, o mu ’wa-rere wa,

 Alejo Olore;

 Gbat’ o ba r’ okan irele

 Lati ma gbe.


4. Tire l’ ohun jeje t’a ngbo,

 Ohun kelekele;

 Ti nbaniwi, ti nl’ eru lo,

 Ti nso t’ orun.


5. Gbogbo iwa-rere t’a nhu,

 Gbogbo isegun wa;

 Gbogbo ero iwa-mimo,

 Tire ni nwon.


6. Emi Mimo, Olutunu,

 F’ iyonu be wa wo;

 Jo s’ okan wa n’ ibugbe Re,

 Ko ye fun O. Amin.


Yoruba Hymn  APA 264 - Olurapada wa, k’On to

This is Yoruba Anglican hymns, APA 264- Olurapada wa, k’On to  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post