Yoruba Hymn APA 279 - Emi ’bukun ti a nsin

Yoruba Hymn APA 279 - Emi ’bukun ti a nsin

 Yoruba Hymn  APA 279 -  Emi ’bukun ti a nsin

APA 279

1. Emi ’bukun ti a nsin

 Pelu Baba at’ Oro,

 Olorun aiyeraiye;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


2. Emi Mimo, ’Daba orun,

 Iri tin se lat’ oke,

 Emi ’ye at’ ina ’fe;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


3. Isun ipa at’ imo,

 Ogbon at’ iwa-mimo,

 Oye, imoran, eru;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


4. Isun ife, Alafia,

 Suru, ibisi ’gbagbo,

 ’Reti, ayo ti ki tan;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


5. Emi Afonahan ni,

 Emi tin mu ’mole wa,

 Emi agbara gbogbo;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


6. ’Wo t’ o mu Wundia bi,

 Eni t’ orun t’ aiye mbo,

 T’a ran lati tun wa bi;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


7. ’Wo ti Jesu t’ oke ran

 Wa tu enia Re ninu,

 Kin won ma ba nikan wa;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


8. ’Wo t’O nf’ ore kun Ijo,

 T’O nfi ife Baba han,

 T’O nmu k’o ma ri Jesu;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


9. Iwo ti nf’ onje iye,

 At’ otito na bo wa,

 Ani, On t’O ku fun wa;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


10. F’ ebun meje Re fun ni,

 Ogbon, lati m’ Olorun,

 Ipa lati ko ota;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


11. Pa ese run lokan wa,

 To ife wa si ona,

 B’a ban se O, mu suru;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


12. Gbe wa dide, b’a subu,

 Ati nigba idanwo,

 Sa pe wa pada pele;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


13. Wa, k’O mu ailera le,

 F’ igboya fun alare,

 Ko wa l’ oror t’a o so;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


14. Wa ran okan wa lowo,

 Lati mo otito Re,

 Ki ’fe wa le ma gbona;

 Emi Mimo, gbo ti wa.


15. Pa wa mo l’ona toro

 Baw a wi nigb’a nsako,

 Ba wa bebe l’ adura,

 Emi Mimo, gbo ti wa.


16. Eni Mimo, Olufe,

 Wa gbe inu okan wa;

 Ma fi wa sile titi:

 Emi Mimo, gbo ti wa. Amin. Yoruba Hymn  APA 279 -  Emi ’bukun ti a nsin

This is Yoruba Anglican hymns, APA 279 - Emi ’bukun ti a nsin  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post