Yoruba Hymn APA 307 - Lala mi po, nko ni ’simi laiye

Yoruba Hymn APA 307 - Lala mi po, nko ni ’simi laiye

Yoruba Hymn  APA 307 - Lala mi po, nko ni ’simi laiye

APA 307

 1. Lala mi po, nko ni ’simi laiye;

 Mo rin jinna, nko r’ ibugbe laiye,

 Nikehin mo wa won laiya Eni

 T’O n’owo Re, t’O si npe alare:

 Lodo Re, mo r’ ile at’ isimi:

 Mo si di Tire, On si di temi.


2. Ire ti mo ni, lat’ odo Re ni;

 B’ ibi ba de, o je b’o ti fe ni;

 B’ On j’ore mi, mo la bi nko ri je,

 L’ aisi Re, mo tosi bi mo l’ oro:

 Ayida le de; ere tab’ ofo;

 O dun mo mi, bi ’m’ bas a je Tire.


3. B’ ayida de, mo mo-On ki yida;

 Orun ogo ti ki ku, ti ki wo;

 O nrin lor’ awosanma at’ iji,

 O ntanmole s’ okunkun enia Re:

 Gbogbo nkan le lo, ko ba mi n’nu je,

 Bi ’m’ ba je Tire, ti On je temi.


4. A! laiye, nko mo idaji ’fe Re;

 Labo ni mo nri, labo ni mo nsin;

 ’Gba mo ba f’ oju kan loke lohun,

 Ngo feran Re po, ngo si yin jojo:

 Ngo wi larin egbe-orin orun,

 Bi mo ti je Tire, t’On je temi. Amin.Yoruba Hymn  APA 307 - Lala mi po, nko ni ’simi laiye

This is Yoruba Anglican hymns, APA 307 - Lala mi po, nko ni ’simi laiye  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post