Yoruba Hymn APA 334 - Oruko kan mbe ti mo fe

Yoruba Hymn APA 334 - Oruko kan mbe ti mo fe

 Yoruba Hymn  APA 334 - Oruko kan mbe ti mo fe

APA 334

1. Oruko kan mbe ti mo fe

 Mo fe ma korin re;

 Iro didun ni l’ eti mi,

 Oruko didun ni.


2. O so ife Olugbala,

 T’ o ku lati ra mi;

 O so t’ eje Re ’yebiye,

 Etutu f’ elese.


3. O so ti iyonu Baba,

 Ti o ni s’ Omo Re;

 O m’ ara mi ya, lati la

 Aginju aiye ja.


4. Jesu, Oruko ti mo fe,

 T’ o si dun l’ eti mi;

 Ko s’ eni mimo kan l’aiye,

 T’ o mo b’ o tip o to.


5. Oruko yi j’ orun didun,

 L’ ona egun t’ a nrin;

 Yio tun ona yangi se,

 T’o lo s’od’ Olorun.


6. Nibe pelu awon mimo,

 Ti nwon bo nin’ ese,

 Emi o korin titun ni,

 T’ ife Jesu si mi. Amin.
Yoruba Hymn  APA 334 - Oruko kan mbe ti mo fe

This is Yoruba Anglican hymns, APA 334-  Oruko kan mbe ti mo fe   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post