Yoruba Hymn APA 374 - Enyin ero, nibo l’ e nlo

Yoruba Hymn APA 374 - Enyin ero, nibo l’ e nlo

 Yoruba Hymn  APA 374 - Enyin ero, nibo l’ e nlo

APA 374

1. “Enyin ero, nibo l’ e nlo,

 T’ enyin t’ opa lowo nyin?

 A nrin ajo mimo kan lo,

 Nipa ase Oba wa.

 Lori oke on petele,

 A nlo s’ afin Oba rere,

 A nlo s’ afin Oba rere,

 A nlo s’ ile t’o dara

 A nlo s’ afin Oba rere,

 A nlo s’ ile t’o dara.


2. Enyin ero, e so fun ni,

 Ti ’reti ti enyin ni?

 Aso mimo, ade ogo,

 Ni Jesu y’o fi fun wa;

 Omi iye l’ a o ma mu;

 A o ba Olorun wa gbe

 A o ba Olorun wa gbe

 N’ ile mimo didara;

 A o ba Olorun wag be

 N’ ile mimo didara.


3. E ko beru ona t’ e nrin,

 Enyin ero kekere?

 `Ore airi npelu wa lo,

 Awon Angel yi wa ka,

 Jesu Kristi l’ amona wa;

 Y’o ma so wa, y’o ma to wa

 Y’o ma so wa, y’o ma to wa

 Ninu ona ajo wa.


4. Ero, a le ban yin kegbe,

 L’ona ajo s’ ile na?

 Wa ma kalo, wa ma kalo,

 Wa si egbe ero wa,

 Wa, e ma se fi wa sile,

 Jesu nduro, o nreti wa,

 Jesu nduro, o nreti wa,

 N’ ile mimo t’ o dara;

 Jesu nduro, o nreti wa,

 N’ ile mimo t’o dara. Amin.



Yoruba Hymn  APA 374 - Enyin ero, nibo l’ e nlo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 374- Enyin ero, nibo l’ e nlo  . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post