Yoruba Hymn APA 400 - Nibo n’ isimi wa

Yoruba Hymn APA 400 - Nibo n’ isimi wa

Yoruba Hymn  APA 400 - Nibo n’ isimi wa

APA 400

 1. Nibo n’ isimi wa

 ’Simi f’ okan are?

 Lasan l’a wa s’opin okun,

 Ati s’ opin ile.


2. Aiye ko le fun ni

 N’ isimi ti a nfe;

 K’a le pe titi laiye ko!

 K’a si tete ku ko!


3. Aiye kan mbe loke,

 T’o jinna s’ aiye yi,

 Nwon ko nsiro odun nibe;

 Ife ni aiye na!


4. Iku mbe, apa re

 Kawo emi wa yi;

 B’ irora kikoro ti to

 Ninu iku keji!


5. Olorun, jo ko wa

 K’a sa fun iku yi;

 K’a ma ba le wa lodo Re,

 K’a si segbe lailai.


6. Nihin l’ ebe wa mo!

 Aiye ife pipe,

 Ati isimi ailopin

 Wa ninu Re nikan. Amin.Yoruba Hymn  APA 400 - Nibo n’ isimi wa

This is Yoruba Anglican hymns, APA 400- Nibo n’ isimi wa . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post