Yoruba Hymn APA 420 - Olori Ijo t’ orun

Yoruba Hymn APA 420 - Olori Ijo t’ orun

Yoruba Hymn  APA 420 - Olori Ijo t’ orun

APA 420

 1. Olori Ijo t’ orun,

 L’ ayo l’ a wole fun O;

 K’ O to de, ijo t’ aiye,

 Y’ o ma korin bi t’ orun.

 A gbe okan wa s’ oke,

 Ni ‘reti t’ o ni ‘bukun;

 Awa kigbe, awa f’ iyin

 F’ Olorun igbala wa.


2. ‘Gbat’ a wa ninu ponju,

 T’ a nkona ninu ina,

 Orin ife l’ awa o ko,

 Ti o nmu wa sunmo O;

 Awa sape, a si yo,

 Ninu ojurere Re;

 Ife t’ o so wa di Tire,

 Y’o se wa ni Tire lai.


3. Iwo mu awon enia Re

 Koja isan idanwo:

 A ki o beru wahala,

 T’ori O wa nitosi:

 Aiye, ese, at’ Esu,

 Kojuja si wa lasan

 L’ agbara Re, a o segun,

 A o si ko orin Mose.


4. Awa f’ igbagbo r’ ogo,

 T’ o tun nfe fi wa si;

 A kegan aiye tori

 Ere nla iwaju wa.

 Bi O ba si ka wa ye,

 Awa pelu Stefen t’ o ku,

 Y’o ri O bi o ti duro,

 Lati pe wa lo s’ orun. Amin.Yoruba Hymn  APA 420 - Olori Ijo t’ orun

This is Yoruba Anglican hymns, APA 420- Olori Ijo t’ orun . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post