Yoruba Hymn APA 431 - Jesu ayo okan gbogbo
APA 431
1. Jesu ayo okan gbogbo,
Orisun ‘ye, imole wa,
Nin’ opo bukun aiye yi,
Lainitelorun: a to wa.
2. Otiti Re duro lailai,
‘Won gb’ awon to kepe O la;
Awon ti o wa O, ri O,
Bi gbogbo nin’ ohun gbogbo.
3. A to O wo, Onje Iye,
A fe je l’ara Re titi;
A mu ninu Re, Orisun,
Lati pa ongbe okan wa.
4. Ongbe Re sa ngbe okan wa,
Nibikibi t’ o wu k’ a wa;
‘Gbat’ a ba ri O awa yo.
A yo nigbat’ a gba O gbo.
5. Jesu, wa ba wa gbe titi,
Se akoko wa ni rere;
Le okunkun ese kuro,
Tan ‘mole Re mimo s’aiye. Amin.
Yoruba Hymn APA 431 - Jesu ayo okan gbogbo
This is Yoruba Anglican hymns, APA 431- Jesu ayo okan gbogbo. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals