Yoruba Hymn APA 430 - Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin

Yoruba Hymn APA 430 - Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin

Yoruba Hymn  APA 430 - Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin

APA 430

 1. “Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin,

 E le ma sore fun won b’e ti nfe.”


2. Eyi ni ogun t’ Olugbala wa

 Fi sile f’ awon Tire, k’o to lo:


3. Wura on jufu ko, otosi ni,

 K’a ma ran won lowo nitori Re.


4. Eru nla ko, ogun t’o l’oro ni

 Ti nf’ ilopo ’bukun f’ eni ntore.


5. T’iwa k’ ise na bi? L’ojude wa

 Ko ni talaka at’ asagbe wa?


6. Ohun irora awon t’ iya nje,

 Ko ha nke si wa lati f’ anu han?


7. Okan t’o gb’ogbe, okan ti nsise;

 Ekun opo, at’ alaini baba!


8. On t’o f’ ara Re fun wa, si ti fi

 Etu orun f’ awa iranse Re.


9. Ko s’otosi kan ti ko le sajo,

 F’eni tosi ju lo; agbara ni.


10. Isin mimo ailabawon l’eyi,

 Ti Baba mbere lowo gbogbo wa. Amin.



Yoruba Hymn  APA 430 - Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin

This is Yoruba Anglican hymns, APA 430- Mo nlo; talaka Mi mbe lodo nyin. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post